Ààrẹ Senegal ṣàbẹ̀wò sí Naijiria, pé fún àjọṣepọ̀ láàrin orílẹ̀èdè Áfíríkà

Aworan Aare orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ati Aarẹ orilẹede Senegal, Bassirou Faye

Oríṣun àwòrán, X/@DOlusegun

Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu gba alejo Aarẹ Bassirou Faye lati orilẹede Senegal niluu Abuja.

Bo ti le jẹ pe a ko le sọ ohun pato to gbe Aarẹ faye wa si orilẹede Naijiria sugbọn ninu ọrọ rẹ, o pe fun ajọṣepọ laarin awọn orilẹede mejeeji ati awọn orilẹede iwọ oorun Afrika.

Aarẹ Faye ni aarẹ to kere lọjọ ju ni iwọ oorun ilẹ Afrika.

Aarẹ orilẹede Naijiria nigba to n gba alejo akẹgbẹ rẹ lati orilẹede Senegal, o ni pe ko ba awọn orilẹede to wa ni tosi, to n gbero lati ya bara kuro ninu ajọ ECOWAS sọrọ, pe ki wọn maa gbe igbesẹ naa.

Awọn orilẹede ti n Aarẹ mẹnu ba ni Burkina Faso, Mali ati Niger ti wọn wa labẹ ijọba ologun, ti wọn si ti lọ da ẹgbẹ mii ti orukọ rẹ n jẹ Alliance of Sahelian State silẹ.

“Gẹgẹ bii alaga ajọ Ecowas, mo n kesi Aarẹ Faye fun ifọwọsowọpọ, ti mo si n rọ pe ko ṣe ipade pẹlu awọn orilẹede yii.

Aworan Aare orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ati Aarẹ orilẹede Senegal, Bassirou Faye

Oríṣun àwòrán, X/@DOlusegun

“Iwọ oorun Afrika gbọdọ sisẹ pọ lati gbe ogun ti awọn iṣoro bii ijinigbe ati iṣẹ”

Aarẹ Bola Tinubu fikun pe “Mo fẹ ki o rọ wọn pe ki wọn pada sinu ajọ Ecowas,”

Bakan naa ni Aarẹ tun pe ajọṣepọ laarin awọn orilẹede to wa ni iwọ oorun ilẹ Afrika lati gbe ogun ti awọn iṣoro to n koju wọn.

“Iwọ oorun ilẹ Afrika gbọdọ sisẹ papọ lati gbe ogun ti awọn iṣoro bii ijinigbe, iṣẹ ati awọn mii to n koju awọn orilẹede.”

Nigba to n sọrọ, Aarẹ Faye dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu, to si tun pe ajọṣepọ laarin orilẹede Senegal ati Naijiria ni ẹka ọrọ aje ati awọn anfani mii.

O ni o ṣe koko ki gbogbo orilẹede Adulawọ fọwọsowọpọ, ki wọn fẹnu bi awọn orilẹede to yẹ baara yii yo ṣe pada sinu ajọ ECOWAS.

Ajọ ECOWAS lo ti n tiraka lati se awọn ẹgbẹ rẹ lọkan lẹyin ti wahala bẹ silẹ ni Sahel.

Iditẹgbajọba waye lorilẹede Niger ninu oṣu keje ọdun 2024,ti wọn fofin de Aarẹ Niamey, ti wọn pẹlu ajọṣepọ pẹlu awọn orilẹede bi Burkina ati Mali, to jẹ ologun lo n dari wọn.